Erinyéyé
Erin Kárelé o wá jọba Ẹ ma jábó Èyin tín gbé ọrí àga gíga tẹ eni kúkúrú mólè A ti mò yín Èyin ògbènù òkùnkùn tafà sínù ìmólè Kò sí àyè fúnnyín Èyin ẹni ibi tín wọso funfun gba èjẹ̀ lára omo owó Owó á tèyín Èyin tín gba ọ̀mìnira lówó alágbára Isé yín á bàjé Èyin tín fúni ní omi ìnira mu torí àtije yìn.